1 Samuel 11:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n sọ fún àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wá láti Jabeṣi-Gileadi pé, “Ẹ sọ fún àwọn eniyan yín pé, ní ọ̀sán ọ̀la, a óo gbà wọ́n kalẹ̀.” Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi gbọ́ ìròyìn náà, inú wọn dùn gidigidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun awọn iranṣẹ na ti o ti wá pe, Bayi ni ki ẹ wi fun awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi; Li ọla, lakoko igbati õrùn ba mu, ẹnyin o ni iranlọwọ. Awọn onṣẹ na wá, nwọn rò o fun awọn ọkunrin Jabeṣi; nwọn si yọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó wá pé, “Sọ fún àwọn ọkùnrin Jabesi-Gílíádì pé, ní àkókò tí oòrùn bá mú lọ́la, àwa yóò gbà yín sílẹ̀.” Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà lọ tí wọ́n sì sọ èyí fún àwọn ọkùnrin Jábésì, inú wọn sì dùn.