1 Samuel 12:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n bá wí fún Samuẹli pé, “Gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ fún wa, kí á má baà kú. Nítorí pé a mọ̀ nisinsinyii pé, yàtọ̀ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti dá tẹ́lẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ tún ni bíbèèrè tí a bèèrè fún ọba tún jẹ́ lọ́rùn wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo enia si wi fun Samueli pe, Gbadura si Oluwa Ọlọrun rẹ fun awọn iranṣẹ rẹ, ki awa ki o má ba kú: nitori ti awa ti fi buburu yi kun gbogbo ẹṣẹ wa ni bibere ọba fun ara wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ènìyàn sì wí fún Sámúẹ́lì pé, “Gbàdúrà sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ kí a má ba à kú, nítorí tí àwa ti fi búburú yìí kún ẹ̀ṣẹ̀ wa ní bí béèrè fún ọba.”