1 Samuel 12:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nisinsinyii, ọba ni yóo máa ṣe olórí yín. Ní tèmi, mo ti dàgbà, ogbó sì ti dé sí mi. Àwọn ọmọ mi sì ń bẹ lọ́dọ̀ yín. Láti ìgbà èwe mi ni mo ti jẹ́ olórí fun yín títí di àkókò yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wõ, nisisiyi, ọba na nrìn niwaju nyin: emi si ti di arugbo, mo si hewu; si wõ, awọn ọmọ mi si mbẹ lọdọ nyin: emi ti nrìn niwaju nyìn lati igba ewe mi wá titi o fi di oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí ẹ ti ní ọba bí olórí yín. Bí ó ṣe tèmi, èmi ti di arúgbó, mo sì ti hewú, àwọn ọmọ mi sì ń bẹ níhìn yìí pẹ̀lú yín. Èmi ti ń ṣe olórí yín láti ìgbà èwe mi wá títí di òní yìí.