1 Samuel 12:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èmi nìyí níwájú yín yìí, bí mo bá ti ṣe nǹkankan tí kò tọ́, ẹ fi ẹ̀sùn kàn mí níwájú OLUWA ati ọba, ẹni àmì òróró rẹ̀. Ǹjẹ́ mo gba mààlúù ẹnikẹ́ni ninu yín rí? Àbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Tabi ta ni mo ni lára rí? Ǹjẹ́ mo gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni rí? Bí mo bá ti ṣe èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan wọnyi rí, mo ṣetán láti san ohun tí mo gbà pada.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wõ, emi nĩ, jẹri si mi niwaju Oluwa, ati niwaju ẹni ami-ororo rẹ̀: malu tani mo gbà ri? tabi kẹtẹkẹtẹ tani mo gbà ri? tani mo rẹjẹ ri? tani mo jẹ ni ìya ri? tabi lọwọ́ tali emi gbà owo abẹtẹlẹ kan ri lati fi bo ara mi loju? emi o si sãn pada fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi dúró níhìn yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú OLÚWA àti níwájú ẹni àmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi ti ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe ìkankan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún un yín.”