1 Samuel 12:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Samuẹli dáhùn pé, “OLUWA ati ọba, ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ gbà pé ọwọ́ mi mọ́ patapata.” Àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, OLUWA ni ẹlẹri wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Oluwa li ẹlẹri si nyin, ati ẹni ami-ororo rẹ̀ ni ẹlẹri loni pe, ẹnyin kò rí nkan lọwọ́ mi. Nwọn si dahùn wipe, On li ẹlẹri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Samúẹ́lì sì wí fún wọn pé, “OLÚWA ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.” Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”