1 Samuel 12:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Jakọbu ati ìdílé rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tí àwọn ará Ijipti ń ni wọ́n lára, àwọn baba ńlá yín kígbe pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA sì rán Mose ati Aaroni, wọ́n kó wọn jáde kúrò ní Ijipti. Ó sì mú kí wọ́n máa gbé orí ilẹ̀ yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Jakobu wá si Egipti, ti awọn baba kigbe pe Oluwa, Oluwa si rán Mose ati Aaroni, awọn ẹniti o mu awọn baba nyin ti ilẹ Egypti jade wá, o si mu wọn joko nihinyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lẹ́yìn ìgbà tí Jákọ́bù wọ Éjíbítì, wọ́n ké pe OLÚWA fún ìrànlọ́wọ́, OLÚWA sì rán Mósè àti Árónì, tí wọ́n mú àwọn baba ńlá yín jáde láti Éjíbítì láti mú wọn jókòó níbí yìí.