1 Samuel 12:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn wọ́n gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn. Wọ́n jagun, OLUWA sì fi wọ́n lé Sisera, olórí ogun Jabini ọba Hasori lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ati ọba Moabu náà sì ṣẹgun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si gbagbe Oluwa Ọlọrun wọn, o si tà wọn si ọwọ́ Sisera, olori ogun Hasori, ati si ọwọ́ awọn Filistini, ati si ọwọ́ ọba Moabu, nwọn si ba wọn jà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbé OLÚWA Ọlọ́run wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tà wọ́n sí ọwọ́ àwọn Sísérà, olórí ogun Hásórì, àti sí ọwọ́ àwọn Fílístínì àti sí ọwọ́ ọba Móábù, tí ó bá wọn jà.