1 Samuel 13:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Samuẹli wí fún un pé, “Kí lo dánwò yìí?” Saulu bá dá a lóhùn pé, “Àwọn eniyan náà ti bẹ̀rẹ̀ sí sá kúrò lẹ́yìn mi, o kò sì dé ní àkókò tí o dá. Àwọn ará Filistia sì ti kó ara wọn jọ ní Mikimaṣi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samueli si bi i pe, Kini iwọ ṣe yi? Saulu si dahùn pe, Nitoriti emi ri pe awọn enia na ntuka kuro lọdọ mi, iwọ kò si wá li akoko ọjọ ti o dá, awọn Filistini si ko ara wọn jọ ni Mikmaṣi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sámúẹ́lì sì wí pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí.” Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn pé, “Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Fílístínì sì kó ara wọ́n jọ ní Míkímásì,