1 Samuel 13:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn nisinsinyii, ìjọba rẹ kò ní jẹ́ títí lae, nítorí pé, o ti ṣe àìgbọràn sí OLUWA. Ó ti wá ẹni tí ó fẹ́, ó sì ti yàn án láti jẹ́ olórí fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé, o kò pa òfin OLUWA rẹ mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nisisiyi ijọba rẹ kì yio duro pẹ: Oluwa ti wá fun ara rẹ̀ ọkunrin ti o wù u li ọkàn rẹ̀, Oluwa paṣẹ fun u ki o ṣe olori fun awọn enia rẹ̀, nitoripe iwọ kò pa aṣẹ ti Oluwa fi fun ọ mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, OLÚWA ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin OLÚWA mọ́.”