1 Samuel 13:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, pẹlu àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pàgọ́ sí Geba ní agbègbè Bẹnjamini. Àgọ́ ti àwọn ará Filistia wà ní Mikimaṣi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu, ati Jonatani ọmọ rẹ̀, ati awọn enia na ti o wà lọdọ wọn si joko ni Gibea ti Benjamini, ṣugbọn awọn Filistini do ni Mikmaṣi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ Jónátanì àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú wọn dúró ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì, nígbà tí àwọn Fílístínì dó ní Míkímásì.