1 Samuel 13:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu yan ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin. Ó fi ẹgbaa (2,000) ninu wọn sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní Mikimaṣi, ní agbègbè olókè ti Bẹtẹli. Ẹgbẹrun (1,000) yòókù wà lọ́dọ̀ Jonatani, ọmọ rẹ̀, ní Gibea, ní agbègbè ẹ̀yà Bẹnjamini. Ó bá dá àwọn yòókù pada sí ilé wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si yan ẹgbẹ̃dogun ọmọkunrin fun ara rẹ̀ ni Israeli; ẹgbã si wà lọdọ Saulu ni Mikmaṣi ati li oke-nla Beteli; ẹgbẹrun si wà lọdọ Jonatani ni Gibea ti Benjamini; o si rán awọn enia ti o kù olukuluku si agọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù yan ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ọkùnrin ní Ísírẹ́lì, ẹgbẹ̀rún méjì (2000) sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Míkimásì àti ní ìlú òkè Bẹ́tẹ́lì ẹgbẹ̀rún kan (1000) sì wà lọ́dọ̀ Jónátanì ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì. Àwọn ọkùnrin tókù ni ó rán padà sí ilé e wọn.