1 Samuel 13:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jonatani ṣẹgun ọ̀wọ́ ọmọ ogun Filistini tí wọ́n wà ní Geba; gbogbo àwọn ará Filistia sì gbọ́ nípa rẹ̀. Saulu bá fọn fèrè ogun jákèjádò ilẹ̀ náà, wí pé “Ẹ jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́ èyí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jonatani si pa ẹgbẹ ogun awọn Filistini ti o wà ninu ile olodi ni Geba, awọn Filistini si gbọ́. Saulu fun ipè yi gbogbo ilẹ na ka, wipe, Jẹ ki awọn Heberu gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jónátánì sì kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Fílístínì ní Gébà, Fílístínì sì gbọ́ èyí. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù fọn ìpè yí gbogbo ilẹ̀ náà ká, ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àwọn Hébérù gbọ́!”