1 Samuel 13:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n ní ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ẹgbaata (6,000) ẹlẹ́ṣin, àwọn ọmọ ogun wọn sì pọ̀ bí eṣú. Wọ́n lọ sí Mikimaṣi ní ìhà ìlà oòrùn Betafeni, wọ́n pàgọ́ wọn sibẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn Filistini kó ara wọn jọ lati ba Israeli jà, ẹgbã-mẹ̃dogun kẹkẹ, ẹgbãta ọkunrin ẹlẹṣin, enia si pọ̀ bi yanrin leti okun; nwọn si goke, nwọn do ni Mikmaṣi ni iha ila õrun Bet-Afeni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn Fílístínì kó ara wọn jọ pọ̀ láti bá Ísírẹ́lì jà, pẹ̀lú ẹgbàá-mẹ́ẹ̀dógún kẹ̀kẹ́, (3000) ẹgbẹ̀ta (6000) ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, àwọn ológun sì pọ̀ bí yanrìn etí òkun. Wọ́n sì gòkè lọ, wọ́n dó ní Míkímásì ní ìhà ilẹ̀ oòrùn Bẹti-Áfénì.