1 Samuel 13:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé ilẹ̀ ti ká àwọn mọ́, nítorí ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini dùn wọ́n, wọ́n bá ń farapamọ́ káàkiri; àwọn kan sá sinu ihò ilẹ̀, àwọn mìíràn sì sá sinu àpáta, inú ibojì ati inú kànga.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin Israeli si ri pe, nwọn wà ninu ipọnju (nitoripe awọn enia na wà ninu ìhamọ) nigbana ni awọn enia na fi ara pamọ ninu iho, ati ninu panti, ninu apata, ni ibi giga, ati ninu kanga gbigbẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàárin àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kàǹga gbígbẹ.