1 Samuel 14:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan, Jonatani, ọmọ Saulu, wí fún ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á lọ sí òdìkejì ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini.” Ṣugbọn Jonatani kò sọ fún Saulu, baba rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li ọjọ kan, Jonatani ọmọ Saulu si wi fun ọdọmọkunrin ti o nru ihamọra rẹ̀, pe, Wá, jẹ ki a rekọja lọ si ibudo-ogun awọn Filistini ti o wà niha keji. Ṣugbọn on kò sọ fun baba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kan, Jónátanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìlú olódi àwọn Fílístínì tí ó wà ní ìhà kejì.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún baba rẹ̀.