1 Samuel 14:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, wọ́n fi ara wọn han àwọn ará Filistia. Bí àwọn ara Filistia ti rí wọn, wọ́n ní, “Ẹ wò ó! Àwọn Heberu ń jáde bọ̀ wá láti inú ihò òkúta tí wọ́n farapamọ́ sí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn mejeji fi ara wọn hàn fun ogun Filistini: awọn Filistini si wipe, Wõ, awọn Heberu ti inu iho wọn jade wá, nibiti nwọn ti fi ara pamọ si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ní àwọn méjèèjì sì fi ara wọn hàn fún ìlú olódi Fílístínì. Àwọn Fílístínì sì wí pé, “Wò ó! Àwọn Hébérù ń fà jáde wá láti inú ihò tí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sí.”