1 Samuel 14:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn ará Filistia tí wọ́n wà ní ibùdó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu pápá, ati gbogbo eniyan. Àwọn ọmọ ogun Filistini ati àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n ń digun-jalè wárìrì, ilẹ̀ mì tìtì, jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibẹ̀ru si wà ninu ogun na, ni pápá, ati ninu gbogbo awọn enia na; ile ọmọ-ogun olodi, ati awọn ti iko ikogun, awọn pẹlu bẹ̀ru; ilẹ sì mi: bẹ̃li o si jasi ọwáriri nlanla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ìbẹ̀rù bojo bá àwọn ọmọ ogun; àwọn tí ó wà ní ibùdó àti ní pápá, àti àwọn tí ó wà ní ilé ìlú olódi àti àwọn tí ń kó ìkógun, ilẹ̀ sì mì. Ó jẹ́ ìbẹ̀rù tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.