1 Samuel 14:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Saulu bá pàṣẹ fún àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n ka gbogbo àwọn ọmọ ogun, láti mọ àwọn tí wọ́n jáde kúrò láàrin wọn. Wọ́n bá ka àwọn ọmọ ogun, wọ́n sì rí i pé Jonatani ati ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ kò sí láàrin wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wi fun awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ pe, Njẹ ẹ kà awọn enia na ki ẹ si mọ̀ ẹniti o jade kuro ninu wa. Nwọn si kà, si kiye si i, Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ kò si si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ ka àwọn ènìyàn kí ẹ sì mọ ẹni tí ó jáde kúrò nínú wa.” Nígbà tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, sì wòó, Jónátanì àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ni kò sì sí níbẹ̀.