1 Samuel 14:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Saulu wí fún Ahija, alufaa pé, “Gbé àpótí Ọlọrun wá níhìn-ín.” Nítorí àpótí Ọlọrun ń bá àwọn ọmọ ogun Israẹli lọ ní àkókò náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wi fun Ahia pe, Gbe apoti Ọlọrun na wá nihinyi. Nitoripe apoti Ọlọrun wà lọdọ awọn ọmọ Israeli li akokò na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Áhíjà pé, “Gbé àpótí Ọlọ́run wá.” Àpótí Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìgbà náà.