1 Samuel 14:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí Saulu ti ń bá alufaa náà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìdàrúdàpọ̀ tí ó wà ninu àgọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini ń pọ̀ sí i. Nítorí náà, Saulu wí fún un pé kí ó dáwọ́ dúró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, bi Saulu ti mba alufa na sọ̀rọ, ariwo ti o wà ni budo awọn Filistini si npọ̀ si i: Saulu si wi fun alufa na pe, dawọ́ duro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì ń bá àlùfáà sọ̀rọ̀, ariwo ní ibùdó àwọn Fílístínì sì ń pọ̀ ṣíwájú sí. Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún àlùfáà pé, “Dá ọwọ́ rẹ dúró.”