1 Samuel 14:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó ara wọn jọ, wọ́n lọ sójú ogun náà. Wọ́n bá àwọn ọmọ ogun ninu ìdàrúdàpọ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ara wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu ati gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀ ko ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá si oju ija: kiye si i, ida olukuluku si wà li ara ọmọnikeji rẹ̀, rudurudu na si pọ̀ gidigidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ sì péjọ, wọ́n sì lọ sí ojú ìjà. Wọ́n sì bá gbogbo àwọn Fílístínì ní ìdàrúdàpọ̀ ńlá, idà olúkúlùkù sì wà lára ọmọ ẹnìkéjì rẹ̀.