1 Samuel 14:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn Heberu tí wọ́n ti wà lẹ́yìn àwọn ará Filistia tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì bá wọn lọ sí ibùdó ogun wọn, yipada kúrò lẹ́yìn wọn, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun Israẹli tí wọ́n wà pẹlu Saulu ati Jonatani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu awọn Heberu ti o wà lọdọ awọn Filistini nigba atijọ, ti o si ti goke ba wọn lọ si budo lati ilu ti o wà yikakiri, awọn na pẹlu si yipada lati dapọ̀ mọ awọn Israeli ti o wà lọdọ Saulu ati Jonatani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn Hébérù tí ó ti wà lọ́dọ̀ àwọn Fílístínì tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti gòkè tẹ̀lé wọn lọ sí àgọ́ wọn wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ti wà pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀lù àti Jónátanì.