1 Samuel 14:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ara àwọn ọmọ ogun Israẹli ti hù ní ọjọ́ náà, àárẹ̀ sì mú wọn, nítorí pé Saulu ti fi ìbúra pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ẹnu kan nǹkankan títí di àṣáálẹ́ ọjọ́ náà, títí tí òun yóo fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá òun, olúwarẹ̀ gbé! Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni ninu wọn tí ó fi ẹnu kan nǹkankan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin Israeli si ri ipọnju gidigidi ni ijọ na: nitoriti Saulu fi awọn enia na bu pe, Ifibu ni fun ẹniti o jẹ onjẹ titi di alẹ titi emi o si fi gbẹsan lara awọn ọta mi. Bẹ̃ni kò si ẹnikan ninu awọn enia na ti o fi ẹnu kan onjẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wà ní ìpọ́njú ńlá ní ọjọ́ náà, nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù ti fi àwọn ènìyàn gégùn ún wí pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ títí di alẹ́, títí èmi yóò fi gbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀ta mi!” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkankan nínú ọ̀wọ́ ogun náà tí ó fi ẹnu kan oúnjẹ.