1 Samuel 14:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Jonatani kò gbọ́ nígbà tí baba rẹ̀ ń fi ìbúra pàṣẹ fún àwọn eniyan náà. Nítorí náà, ó na ọ̀pá tí ó mú lọ́wọ́, ó tì í bọ inú afárá oyin kan, ó sì lá a. Lẹsẹkẹsẹ ojú rẹ̀ wálẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Jonatani kò gbọ́ nigbati baba rẹ̀ fi ifibu kilọ fun awọn enia na: o si tẹ ori ọpa ti mbẹ lọwọ rẹ̀ bọ afara oyin na, o si fi i si ẹnu rẹ̀, oju rẹ̀ mejeji si walẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Jónátanì kò gbọ́ pé baba rẹ̀ ti fi ègún kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ orí ọ̀pá tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bọ afárá oyin náà, ó sì fi sí ẹnu rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dán.