1 Samuel 14:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni tí ó jẹ́ alufaa tí ó ń wọ ẹ̀wù efodu nígbà náà ni Ahija, ọmọ Ahitubu, arakunrin Ikabodu, ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, tíí ṣe alufaa OLUWA ní Ṣilo. Àwọn ọmọ ogun kò mọ̀ pé Jonatani ti kúrò lọ́dọ̀ àwọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ahia ọmọ Ahitubu, arakunrin Ikabodu ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, alufa Oluwa ni Ṣilo, ti nwọ̀ Efodu. Awọn enia na kò si mọ̀ pe Jonatani ti lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
lára wọn ni Áhíjà, tí ó wọ Éfódù. Òun ni ọmọ arákùnrin Íkábódù Áhítúbì, ọmọ Fínéhásì, ọmọ Élì, àlùfáà OLÚWA ní Ṣílò kò sí ẹni tí ó mọ̀ pé Jónátanì ti lọ.