1 Samuel 14:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó tún pàṣẹ pé, “Ẹ lọ sí ààrin àwọn eniyan, kí ẹ sì wí fún wọn pé, kí wọ́n kó mààlúù wọn ati aguntan wọn wá síhìn-ín. Níhìn-ín ni kí wọ́n ti pa wọ́n, kí wọ́n sì jẹ wọ́n. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀, kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA.” Nítorí náà, gbogbo wọn kó mààlúù wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Saulu ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wipe, Ẹ tu ara nyin ka sarin awọn enia na ki ẹ si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ọkunrin mu malu tirẹ̀ tọ̀ mi wá, ati olukuluku ọkunrin agutan rẹ̀, ki ẹ si pa wọn nihin, ki ẹ si jẹ, ki ẹ má si ṣẹ̀ si Oluwa, ni jijẹ ẹjẹ. Gbogbo enia olukuluku ọkunrin mu malu rẹ̀ wá li alẹ na, nwọn si pa wọn ni ibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ó wí pé, “Ẹ jáde lọ sáàrín àwọn ènìyàn náà kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Kí olúkúlùkù wọn mú màlúù àti àgùntàn tirẹ̀ tọ̀ mí wá, kí wọ́n sì pa wọ́n níhìn, kí wọ́n sì jẹ́. Ẹ má ṣe ṣẹ̀ sí OLÚWA, kí ẹ má ṣe jẹ ẹran tòun tẹ̀jẹ̀.’ ” Bẹ́ẹ̀ ní olúkúlùkù mú màlúù tirẹ̀ wá ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀.