1 Samuel 14:37 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Saulu bá bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun pé, “Ṣé kí n lọ kọlu àwọn ará Filistia? Ṣé o óo fún Israẹli ní ìṣẹ́gun?” Ṣugbọn Ọlọrun kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si bere lọdọ Ọlọrun pe, ki emi ki o sọkalẹ tọ̀ awọn Filistini lọ bi? Iwọ o fi wọn lé Israeli lọwọ́ bi? ṣugbọn kò da a lohùn li ọjọ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé, “Ṣé kí n sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn Fílístínì lọ bí? Ǹjẹ́ ìwọ yóò fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ bí?” Ṣùgbọ́n OLÚWA kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà.