1 Samuel 14:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn òkúta ńláńlá meji kan wà ní ọ̀nà kan, tí ó wà ní àfonífojì Mikimaṣi. Pàlàpálá òkúta wọnyi ni Jonatani gbà lọ sí ibùdó ogun àwọn Filistini. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn òkúta náà wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ọ̀nà náà. Orúkọ ekinni ń jẹ́ Bosesi, ekeji sì ń jẹ́ Sene.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Larin meji ọ̀na wọnni, eyi ti Jonatani ti nwá lati lọ si ile ọmọ-ogun olodi ti Filistini, okuta mimú kan wà li apa kan, okuta mímú kan si wà li apa keji: orukọ ekini si njẹ Bosesi, orukọ ekeji si njẹ Sene.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọ̀nà tí Jónátanì ti ń fẹ́ láti kọjá dé ìlú olódi àwọn Fílístínì, ní bèbè òkúta mímú kan wá, orúkọ èkíní sì ń jẹ́ Bóṣéṣì, orúkọ èkejì sì ń jẹ́ Sénè.