1 Samuel 14:41 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu bá ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí o kò fi dá iranṣẹ rẹ lóhùn lónìí? OLUWA Ọlọrun Israẹli, bí ó bá jẹ́ pé èmi tabi Jonatani ni a jẹ̀bi, fi Urimu dáhùn. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé àwọn eniyan rẹ ni wọ́n ṣẹ̀, fi Tumimu dáhùn.” Urimu bá mú Jonatani ati Saulu,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wi fun Oluwa Ọlọrun Israeli pe, fun mi ni ibò ti o pé. A si mu Saulu ati Jonatani: ṣugbọn awọn enia na yege.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù gbàdúrà sí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì pé, “Fún mi ní ìdáhùn tí ó tọ́.” A sì mú Jónátanì àti Ṣọ́ọ̀lù nípa ìbò dídì, àwọn ènìyàn náà sì yege.