1 Samuel 14:45 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni àwọn eniyan wí fún Saulu pé, “Ṣé a óo pa Jonatani ni, ẹni tí ó ti ṣẹ́ ogun ńlá fún Israẹli? Kí á má rí i. Bí OLUWA tí ń bẹ láàyè, ẹyọ irun orí rẹ̀ kan kò ní bọ́ sílẹ̀. Agbára Ọlọrun ni ó fi ṣe ohun tí ó ṣe lónìí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan náà ṣe gba Jonatani kalẹ̀, tí wọn kò sì jẹ́ kí wọ́n pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia si wi fun Saulu pe, Jonatani yio kú, ti o ṣe igbala nla yi ni Israeli? ki a má ri i; bi Oluwa ti wà, ọkan ninu irun ori rẹ̀ kì yio bọ́ silẹ; nitoripe o ba Ọlọrun ṣiṣẹ pọ̀ loni. Bẹ̃li awọn enia si gbà Jonatani silẹ, kò si kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí Jónátanì kú, ẹni tí ó ti mú ìgbàlà ńlá yìí wá fún Ísírẹ́lì? Kí a má rí í! Bí OLÚWA ti wà, ọ̀kan nínú irun orí rẹ̀ kì yóò bọ́ sílẹ̀, nítorí tí ó ṣe èyí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́.” Báyìí ni àwọn ènìyàn gba Jónátanì sílẹ̀, kò sì kú.