1 Samuel 14:47 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn tí Saulu ti di ọba Israẹli tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọ̀tá tí wọ́n yí i ká jagun; àwọn bíi: Moabu, Amoni, ati Edomu, ọba ilẹ̀ Soba, ati ti ilẹ̀ Filistini. Ní gbogbo ibi tí ó ti jagun ni ó ti pa wọ́n ní ìpakúpa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si jọba lori Israeli; o si bá gbogbo awọn ọta rẹ̀ jà yika, eyini ni Moabu ati awọn ọmọ Ammoni, ati Edomu, ati awọn ọba Soba ati awọn Filistini: ati ibikibi ti o yi si, a bà wọn ninu jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí Ṣọ́ọ̀lù ti jọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì bá gbogbo ọ̀tá wọn jà yíká: Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì; Édómù, àti àwọn ọba Ṣọ́bà, àti àwọn Fílístínì. Ibikíbi tí ó bá kọjú sí, ó máa ń fi ìyà jẹ wọ́n.