1 Samuel 14:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jonatani bá pe ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó ní, “Jẹ́ kí á rékọjá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Filistia, àwọn aláìkọlà wọnyi, bóyá OLUWA a jẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Bí OLUWA bá fẹ́ ran eniyan lọ́wọ́, kò sí ohun tí ó lè dí i lọ́wọ́, kì báà jẹ́ pé eniyan pọ̀ ni, tabi wọn kò pọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jonatani wi fun ọdọmọdekunrin ti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Wá, si jẹ ki a lọ si budo-ogun awọn alaikọla yi: bọya Oluwa yio ṣiṣẹ fun wa: nitoripe kò si idiwọ fun Oluwa lati fi pipọ tabi diẹ gba là.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jónátanì sì wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ìlu olódi àwọn aláìkọlà yìí. Bóyá OLÚWA yóò jà fún wa, kò sí ohun tó lè di OLÚWA lọ́wọ́ láti gbàlà, yálà nípaṣẹ̀ púpọ̀ tàbí nípaṣẹ̀ díẹ̀.”