1 Samuel 15:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ó dùn mí pé mo fi Saulu jọba. Ó ti yipada kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa òfin mi mọ́.” Inú bí Samuẹli, ó sì gbadura sí OLUWA ní gbogbo òru ọjọ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi kãnu gidigidi ti emi fi Saulu jọba: nitoriti o ti yipada lẹhin mi, kò si mu ọ̀rọ mi ṣẹ. O si ba Samueli ninu jẹ gidigidi; on si kepe Oluwa ni gbogbo oru na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi káànú gidigidi pé mo fi Ṣọ́ọ̀lù jọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Inú Sámúẹ́lì sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì képe OLÚWA ní gbogbo òru náà.