1 Samuel 15:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ keji, ó jáde, ó lọ rí Saulu. Ó gbọ́ pé Saulu ti lọ sí Kamẹli, níbi tí ó ti gbé ọ̀wọ̀n kan kalẹ̀, ní ìrántí ara rẹ̀, ati pé ó ti gba ibẹ̀ lọ sí Giligali.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Samueli si dide ni kutukutu owurọ̀ lati pade Saulu, nwọn si sọ fun Samueli pe, Saulu ti wá si Karmeli, sa wõ, on kọ ibi kan fun ara rẹ̀ o si ti lọ, o si kọja siwaju, o si sọkalẹ lọ si Gilgali.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Sámúẹ́lì sì dìde láti lọ pàdé Ṣọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún un pé, “Ṣọ́ọ̀lù ti wá sí Kámẹ́lì. Ó ti kọ́ ibìkan fún ara rẹ̀ níbẹ̀, ó sì ti yípadà, ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Gílígálì.”