1 Samuel 15:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sì rán ọ jáde pẹlu àṣẹ pé kí o pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ará Amaleki run. Ó ní kí o gbógun tì wọ́n títí o óo fi pa wọ́n run patapata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si rán ọ ni iṣẹ, o si wipe, Lọ, ki o si pa awọn ẹlẹṣẹ ara Amaleki run, ki o si ba wọn jà titi o fi run wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì rán ọ níṣẹ́ wí pé, ‘Lọ, kí o sì pa àwọn ènìyàn búburú ará Ámálékì run pátapáta; gbógun tì wọ́n títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’