1 Samuel 15:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu dá a lóhùn pé, “Mo ti pa òfin OLUWA mọ́, mo jáde lọ bí o ti wí fún mi pé kí n jáde lọ, mo mú Agagi ọba pada bọ̀, mo sì pa gbogbo àwọn ará Amaleki run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wi fun Samueli pe, Nitotọ, emi gbà ohùn Oluwa gbọ́, emi si ti lọ li ọ̀na ti Oluwa ran mi, emi si ti mu Agagi ọba Amaleki wá, emi si ti pa ara Amaleki run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Sámúẹ́lì pé, “Ṣùgbọ́n èmi ti ṣe ìgbọ́rán sí OLÚWA, èmi sì ti lọ ní ọ̀nà tí OLÚWA rán mi. Mo sì ti pa àwọn ará Ámálékì run pátapáta, mo sì ti mú Ágágì ọba wọn padà wá.