1 Samuel 15:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn eniyan mi ni wọ́n kó ìkógun aguntan ati àwọn mààlúù tí ó dára jùlọ lára àwọn ohun tí a ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun láti fi wọ́n rúbọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ ní Giligali.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn enia na ti mu ninu ikogun, agutan ati malu, pàtaki nkan wọnni ti a ba pa run, lati fi rubọ si Oluwa Ọlọrun rẹ ni Gilgali.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ ogun ti mú àgùntàn àti màlúù lára ìkógùn èyí tí ó dára láti fi fún OLÚWA láti fi rúbọ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ní Gílígálì.”