1 Samuel 15:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni tí ń ṣe oríkunkun sí OLUWA ati ẹni tí ó ṣẹ́ṣó, bákan náà ni wọ́n rí; ẹ̀ṣẹ̀ ìgbéraga ati ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà kò sì yàtọ̀. Nítorí pé, o kọ òfin OLUWA, OLUWA ti kọ ìwọ náà ní ọba.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe iṣọtẹ dabi ẹ̀ṣẹ afọṣẹ, ati agidi gẹgẹ bi ìwa buburu ati ibọriṣa. Nitoripe iwọ kọ̀ ọ̀rọ Oluwa, on si kọ̀ ọ li ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ, àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà. Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ OLÚWA, Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.”