1 Samuel 15:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu wí fún Samuẹli pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo ti dẹ́ṣẹ̀. Mo ti ṣe àìgbọràn sí òfin OLUWA ati sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí pé mo bẹ̀rù àwọn eniyan mi, mo sì ṣe ohun tí wọ́n fẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wi fun Samueli pe, Emi ti ṣẹ̀: nitoriti emi ti re ofin Oluwa kọja, ati ọ̀rọ rẹ̀: nitori emi bẹ̀ru awọn enia, emi si gbà ohùn wọn gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún Sámúẹ́lì pé, “Èmi ti ṣẹ̀. Mo ti rú òfin OLÚWA àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi sì bẹ̀rù àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni èmi sì gba ohùn wọn gbọ́.