1 Samuel 15:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lọ gbógun ti àwọn ará Amaleki, kí o sì run gbogbo nǹkan tí wọ́n ní patapata. O kò gbọdọ̀ dá nǹkankan sí, pa gbogbo wọn, atọkunrin, atobinrin; àtàwọn ọmọ kéékèèké; àtàwọn ọmọ ọmú; ati mààlúù, ataguntan, ati ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, gbogbo wọn pátá ni kí o pa.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lọ nisisiyi ki o si kọlu Amaleki, ki o si pa gbogbo nkan wọn li aparun, má si ṣe da wọn si; ṣugbọn pa ati ọkunrin ati obinrin wọn, ọmọ kekere ati awọn ti o wà li ẹnu ọmu, malu ati agutan, ibakasiẹ ati kẹtẹkẹtẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lọ nísinsìn yìí, kí o sì kọlu Ámálékì, kí o sì pa gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ ti wọn ní àparun. Má ṣe dá wọn sí, pa ọkùnrin àti obìnrin wọn, ọmọ kékeré àti ọmọ ọmú, màlúù àti àgùntàn, ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn.”