1 Samuel 15:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu dá a lóhùn pé, “Mo mọ̀ pé mo ti ṣẹ̀, ṣugbọn bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbààgbà, àwọn eniyan mi ati gbogbo Israẹli. Bá mi pada lọ, kí n lọ sin OLUWA Ọlọrun rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, emi ti dẹ̀ṣẹ: ṣugbọn bu ọlá fun mi, jọwọ, niwaju awọn agbãgbà enia mi, ati niwaju Israeli, ki o si tun yipada pẹlu mi, ki emi ki o le tẹriba niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Èmi ti ṣẹ̀, ṣùgbọ́n jọ̀wọ́ bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbààgbà ènìyàn mi, àti níwájú u Ísírẹ́lì, yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè tẹríba fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ.”