1 Samuel 15:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Samuẹli bá sọ fún un pé, “Bí idà rẹ ti sọ ọpọlọpọ ìyá di aláìlọ́mọ, bẹ́ẹ̀ ni ìyá tìrẹ náà yóo di aláìlọ́mọ láàrin àwọn obinrin.” Samuẹli bá gé Agagi wẹ́lẹwẹ̀lẹ níwájú pẹpẹ ní Giligali.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samueli si wipe, Gẹgẹ bi idà rẹ ti sọ awọn obinrin di alaili ọmọ, bẹ̃ gẹgẹ ni iya rẹ yio si di alaili ọmọ larin obinrin. Samueli si pa Agagi niwaju Oluwa ni Gilgali.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, “Bí idà rẹ ti sọ àwọn obìnrin di aláìní ọmọ bẹ́ẹ̀ ni ìyá rẹ yóò sì di aláìní ọmọ láàárin obìnrin.” Sámúẹ́lì sì pa Ágágì níwájú OLÚWA ni Gílígálì.