1 Samuel 15:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu ranṣẹ ìkìlọ̀ kan sí àwọn ará Keni pé, “Ẹ jáde kúrò láàrin àwọn ará Amaleki, kí n má baà pa yín run, nítorí pé ẹ̀yin ṣàánú àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti.” Àwọn ará Keni bá jáde kúrò láàrin àwọn ará Amaleki.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wi fun awọn Keniti pe, Ẹ lọ, yẹra kuro larin awọn ara Amaleki, ki emi ki o má ba run nyin pẹlu wọn: nitoripe ẹnyin ṣe ore fun gbogbo awọn ọmọ Israeli nigbati nwọn goke ti Egipti wá. Awọn Keniti yẹra kuro larin Amaleki.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ó wí fún àwọn Kénáítì pé, “Ẹ lọ, kúrò ní Ámálékì kí èmi má ba à run yín pẹ̀lú wọn; nítorí ẹ̀yin fi àánú hàn fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n gòkè ti Éjíbítì wá.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Kénáítì lọ kúrò láàrin àwọn Ámálékì.