1 Samuel 15:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ dá Agagi sí, wọn kò sì pa àwọn tí wọ́n dára jùlọ ninu àwọn aguntan, mààlúù, ati ọ̀dọ́ mààlúù ati ọ̀dọ́ aguntan wọn, ati àwọn nǹkan mìíràn tí ó dára. Wọn kò pa wọ́n run, ṣugbọn wọ́n pa àwọn ohun tí kò níláárí run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Saulu ati awọn enia na da Agagi si, ati eyi ti o dara julọ ninu agutan ati ninu malu, ati ohun eyi ti o dara tobẹ̃ ninu wọn, ati ọdọ-agutan abọpa, ati gbogbo nkan ti o dara; nwọn kò si fẹ pa wọn run: ṣugbọn gbogbo nkan ti kò dara ti kò si nilari ni nwọn parun patapata.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dá Ágágì sí àti èyí tí ó dára jùlọ nínú àgùntàn àti màlúù àti ọ̀dọ́ àgùntàn àbọ́pa àti gbogbo nǹkan tó dára. Wọ́n kò sì fẹ́ pa àwọn wọ̀nyí run pátapáta ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan tí kò dára tí kò sì ní láárí ni wọ́n parun pátapáta.