1 Samuel 16:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Samuẹli bá bèèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin nìyí?” Jese dáhùn, ó ní, “Ó ku èyí tí ó kéré jù, ṣugbọn ó ń tọ́jú agbo ẹran.” Samuẹli bá wí fún Jese, pé, “Ranṣẹ lọ pè é wá, nítorí pé a kò ní jókòó títí yóo fi dé.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samueli si bi Jesse lere pe, gbogbo awọn ọmọ rẹ li o wà nihin bi? On si dahun wipe, abikẹhin wọn li o kù, sa wõ, o nṣọ agutan. Samueli si wi fun Jesse pe, Ranṣẹ ki o si mu u wá: nitoripe awa kì yio joko titi on o fi dé ihinyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ó béèrè lọ́wọ́ Jésè pé, “Ṣé èyí ni gbogbo àwọn ọmọ rẹ?” Jésè dáhùn pé, “Ó ku àbíkẹ́yìn wọn, ó ń tọ́jú agbo àgùntàn.” Sámúẹ́lì sì wí pé, “Rán ìránṣẹ́ lọ pè é wá; àwa kò ní jókòó títí òun yóò fi dé.”