1 Samuel 16:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀mí OLUWA kúrò lára Saulu, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ OLUWA sì ń dà á láàmú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Ẹmi Oluwa fi Saulu silẹ, ẹmi buburu lati ọdọ Oluwa si nyọ ọ li ẹnu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí, ẹ̀mi OLÚWA ti kúrò lára Ṣọ́ọ̀lù, ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ OLÚWA sì ń yọ ọ́ lẹ́nu.