1 Samuel 16:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Wò ó! Mo ti rí ọmọ Jese ará Bẹtilẹhẹmu tí ó mọ hapu ta dáradára. Ó jẹ́ alágbára ati akọni lójú ogun, ó ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu, ó lẹ́wà, OLUWA sì wà pẹlu rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkan ninu iranṣẹ wọnni si dahùn wipe, Wõ emi ri ọmọ Jesse kan ti Betlehemu ti o mọ̀ iṣẹ orin, o si jẹ ẹni ti o li agbara gidigidi, ati ologun, ati ẹni ti o ni ọgbọ́n ọ̀rọ isọ, ati arẹwa, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀kan nínú ìránṣẹ́ náà dáhùn pé, “Èmi ti ri ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Jésè ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó mọ orin kọ, ó jẹ́ alágbára àti ológun. Ó ní ọgbọ́n ọ̀rọ̀ òun sì dára ní wíwò. OLÚWA sì wà pẹ̀lú u rẹ̀.”