1 Samuel 16:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Samuẹli dáhùn pé, “Báwo ni n óo ṣe lọ? Bí Saulu bá gbọ́, pípa ni yóo pa mí.” OLUWA dá a lóhùn pé, “Mú ọ̀dọ́ mààlúù kan lọ́wọ́, kí o wí pé o wá rúbọ sí OLUWA ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samueli si wi pe, Emi o ti ṣe lọ? bi Saulu ba gbọ́ yio si pa mi. Oluwa si wi fun u pe, mu ọdọ-malu kan li ọwọ́ rẹ, ki o si wipe, Emi wá rubọ si Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé; “Báwo ni èmi yóò ṣe lọ? Bí Ṣọ́ọ̀lù bá gbọ́ nípa rẹ̀, yóò pa mi.” OLÚWA wí pé, “Mú abo ẹgbọ̀rọ̀ màlúù kan pẹ̀lú rẹ, kí o sì wí pé, ‘Èmi wá láti wá rúbọ sí OLÚWA.’