1 Samuel 16:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Samuẹli ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún un, ó lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Gbígbọ̀n ni àwọn àgbààgbà ìlú bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n bí wọ́n ti ń lọ pàdé rẹ̀. Wọ́n bi í pé, “Ṣé alaafia ni?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samueli si ṣe eyi ti Oluwa wi fun u, o sì wá si Betlehemu. Awọn agbà ilu na si bẹ̀ru nitori wiwá rẹ̀, nwọn si wipe, Alafia ki iwọ ba wá si bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sámúẹ́lì ṣe ohun tí OLÚWA sọ. Nígbà tí ó dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àyà gbogbo àgbààgbà ìlú já, nígbà tí wọ́n pàdé rẹ̀. Wọ́n béèrè pé, “Ṣé àlàáfíà ní ìwọ bá wá?”