1 Samuel 16:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Samuẹli dáhùn pé, “Alaafia ni. Ẹbọ ni mo wá rú sí OLUWA. Ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ bá mi lọ síbi ìrúbọ náà.” Ó ya Jese ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, ó sì pè wọ́n síbi ìrúbọ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si dahùn wipe, Alafia ni: emi wá rubọ si Oluwa; ẹ ṣe ara nyin ni mimọ́, ki ẹ si wá pẹlu mi si ibi ẹbọ na. On si yà Jesse sí mimọ́, ati awọn ọmọ rẹ̀, o si pe wọn si ẹbọ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sámúẹ́lì sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà ni; mo wá láti wá rúbọ sí OLÚWA. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì wá rúbọ pẹ̀lú ù mi.” Nígbà náà ni ó sì ya Jésè sí mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì pè wọ́n wá sí ibi ìrúbọ náà.